1 Mo si wò, si kiyesi i, Ọdọ-Agutan na duro lori òke Sioni, ati pẹlu rẹ̀ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, nwọn ni orukọ rẹ̀, ati orukọ Baba rẹ̀ ti a kọ si iwaju wọn.
2 Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá, bi ariwo omi pupọ̀, ati bi sisán ãrá nla: mo si gbọ́ awọn aludùru, nwọn nlù dùru wọn:
3 Nwọn si nkọ bi ẹnipe orin titun niwaju itẹ́ nì, ati niwaju awọn ẹda alãye mẹrin nì, ati awọn àgba nì: ko si si ẹniti o le kọ́ orin na, bikoṣe awọn ọkẹ́ meje o le ẹgbaji enia, ti a ti rà pada lati inu aiye wá.
4 Awọn wọnyi li a kò fi obinrin sọ di ẽri; nitoripe wundia ni nwọn. Awọn wọnyi ni ntọ̀ Ọdọ-Agutan na lẹhin nibikibi ti o ba nlọ. Awọn wọnyi li a rà pada lati inu awọn enia wá, nwọn jẹ́ akọso fun Ọlọrun ati fun Ọdọ-Agutan na.