10 On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ̀; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan:
11 Ẹ̃fin oró wọn si nlọ soke titi lailai, nwọn kò si ni isimi li ọsán ati li oru, awọn ti nforibalẹ fun ẹranko na ati fun aworan rẹ̀, ati ẹnikẹni ti o ba si gbà àmi orukọ rẹ̀.
12 Nihin ni sũru awọn enia mimọ́ gbé wà: awọn ti npa ofin Ọlọrun ati igbagbọ́ Jesu mọ́.
13 Mo si gbọ́ ohùn kan lati ọrun wá nwi fun mi pe, Kọwe rẹ̀, Alabukún fun li awọn okú ti o kú nipa ti Oluwa lati ìhin lọ: Bẹni, li Ẹmí wi, ki nwọn ki o le simi kuro ninu lãlã wọn, nitori iṣẹ wọn ntọ̀ wọn lẹhin.
14 Mo si wò, si kiyesi i, awọsanma funfun kan, ati lori awọsanma na ẹnikan joko ti o dabi Ọmọ-enia, ti on ti ade wura li ori rẹ̀, ati dòjé mimú li ọwọ́ rẹ̀.
15 Angẹli miran si ti inu tẹmpili jade wá ti nke li ohùn rara si ẹniti o joko lori awọsanma pe, Tẹ̀ doje rẹ bọ̀ ọ, ki o si mã kore: nitori akokò ati kore de, nitori ikorè aiye ti gbó tan.
16 Ẹniti o joko lori awọsanma na si tẹ̀ doje rẹ̀ bọ̀ ori ilẹ aiye; a si ṣe ikore ilẹ aiye.