2 Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye.
3 O si gbe mi ninu Ẹmí lọ si aginjù: mo si ri obinrin kan o joko lori ẹranko alawọ̀ odòdó kan ti o kún fun orukọ ọrọ-odi, o ni ori meje ati iwo mẹwa.
4 A si fi aṣọ elese aluko ati aṣọ odòdó wọ obinrin na, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perli ṣe e lọṣọ́, o ni ago wura kan li ọwọ́ rẹ̀, ti o kún fun irira ati fun ẹgbin àgbere rẹ̀:
5 Ati niwaju rẹ̀ ni orukọ kan ti a kọ, OHUN IJINLẸ, BABILONI NLA, IYA AWỌN PANṢAGA ATI AWỌN OHUN IRIRA AIYE.
6 Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi.
7 Angẹli si wi fun mi pe, Nitori kili ẹnu ṣe yà ọ? emi o sọ ti ijinlẹ obinrin na fun ọ, ati ti ẹranko ti o gùn, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa.
8 Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá.