1 MO si ri angẹli kan nti ọrun sọkalẹ wá, ti on ti ìṣika ọgbun nì, ati ẹ̀wọn nla kan li ọwọ́ rẹ̀.
2 O si di dragoni na mu, ejò atijọ nì, ti iṣe Èṣu, ati Satani, o si dè e li ẹgbẹ̀run ọdún.
3 O si gbé e sọ sinu ọgbun na, o si ti i, o si fi èdidi di i lori rẹ̀, ki o má bã tan awọn orilẹ-ède jẹ mọ́ titi ẹgbẹrun ọdún na yio fi pé: lẹhin eyi, a kò le ṣai tu u silẹ fun igba diẹ.
4 Mo si ri awọn ìtẹ́, nwọn si joko lori wọn, a si fi idajọ fun wọn: mo si ri ọkàn awọn ti a ti bẹ́ lori nitori ẹrí Jesu, ati nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati awọn ti kò si foribalẹ fun ẹranko na, ati fun aworan rẹ̀, tabi ti kò si gbà àmi rẹ̀ ni iwaju wọn ati li ọwọ́ wọn; nwọn si wà lãye, nwọn si jọba pẹlu Kristi li ẹgbẹrun ọdún.
5 Awọn okú iyokù kò wà lãye mọ́ titi ẹgbẹ̀run ọdún na yio fi pé. Eyi li ajinde ekini.
6 Olubukun ati mimọ́ ni ẹniti o ni ipa ninu ajinde ekini na: lori awọn wọnyi ikú ekeji kò li agbara, ṣugbọn nwọn o jẹ alufa Ọlọrun ati ti Kristi, nwọn o si mã jọba pẹlu rẹ̀ li ẹgbẹ̀run ọdún.