20 Ẹkarun, sardoniki; ẹkẹfa, sardiu; ekeje, krisoliti; ẹkẹjọ berili; ẹkẹsan, topasi; ẹkẹwa, krisoprasu; ẹkọkanla, hiakinti; ekejila, ametisti.
21 Ẹnubode mejejila jẹ perli mejila: olukuluku ẹnubode jẹ perli kan; ọ̀na igboro ilu na si jẹ kìki wura, o dabi digí didán.
22 Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan.
23 Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀.
24 Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀.
25 A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀.
26 Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀.