22 Emi kò si ri tẹmpili ninu rẹ̀: nitoripe Oluwa Ọlọrun Olodumare ni tẹmpili rẹ̀, ati Ọdọ-Agutan.
23 Ilu na kò si ni iwá õrùn, tabi oṣupa, lati mã tan imọlẹ si i: nitoripe ogo Ọlọrun li o ntàn imọlẹ si i, Ọdọ-Agutan si ni fitila rẹ̀.
24 Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀.
25 A kì yio si sé awọn ẹnubode rẹ̀ rara li ọsán: nitori kì yio si oru nibẹ̀.
26 Nwọn o si ma mu ogo ati ọlá awọn orilẹ-ède wá sinu rẹ̀.
27 Ohun alaimọ́ kan kì yio si wọ̀ inu rẹ̀ rara, tabi ohun ti nṣiṣẹ irira ati eke; bikoṣe awọn ti a kọ sinu iwe ìye Ọdọ-Agutan.