16 Emi Jesu li o rán angẹli mi lati jẹri nkan wọnyi fun nyin niti awọn ijọ. Emi ni gbòngbo ati iru-ọmọ Dafidi, ati irawọ owurọ̀ ti ntàn.
17 Ati Ẹmí ati iyawo wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti o ngbọ́ ki o wipe, Mã bọ̀. Ati ẹniti ongbẹ ngbẹ ki o wá. Ẹnikẹni ti o ba si fẹ, ki o gbà omi ìye na lọfẹ.
18 Emi njẹri fun olukuluku ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ isọtẹlẹ iwe yi pe, Bi ẹnikẹni ba fi kún wọn, Ọlọrun yio fi kún awọn iyọnu ti a kọ sinu iwe yi fun u.
19 Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọ̀rọ iwe isọtẹlẹ yi, Ọlọrun yio si mu ipa tirẹ̀ kuro ninu iwe ìye, ati kuro ninu ilu mimọ́ nì, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu iwe yi.
20 Ẹniti o jẹri nkan wọnyi wipe, Nitõtọ emi mbọ̀ kánkán; Amin. Mã bọ̀, Jesu Oluwa.
21 Ore-ọfẹ Jesu Oluwa ki o wà pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́. Amin.