1 MO si ri li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na, iwe kan ti a kọ ninu ati lẹhin, ti a si fi èdidi meje dì.
2 Mo si ri angẹli alagbara kan, o nfi ohùn rara kede pe, Tali o yẹ lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀?
3 Kò si si ẹnikan li ọrun, tabi lori ilẹ aiye, tabi nisalẹ ilẹ, ti o le ṣí iwe na, tabi ti o le wò inu rẹ̀.
4 Emi si sọkun gidigidi, nitoriti a kò ri ẹnikan ti o yẹ lati ṣí ati lati kà iwe na, tabi lati wò inu rẹ̀.
5 Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje.