1 EMI si ri nigbati Ọdọ-Agutan na ṣí ọ̀kan ninu èdidi wọnni, mo si gbọ́ ọ̀kan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì nwi bi ẹnipe sisan ãrá pe, Wá, wò o.
2 Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin funfun kan: ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni ọrun kan; a si fi ade kan fun u: o si jade lọ lati iṣẹgun de iṣẹgun.
3 Nigbati o si ṣí èdidi keji, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye keji nwipe, Wá, wò o.
4 Ẹṣin miran ti o pupa si jade: a si fi agbara fun ẹniti o joko lori rẹ̀, lati gbà alafia kuro lori ilẹ aiye, ati pe ki nwọn ki o mã pa ara wọn: a si fi idà nla kan le e lọwọ.
5 Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀.
6 Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara.
7 Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o.