4 Ẹṣin miran ti o pupa si jade: a si fi agbara fun ẹniti o joko lori rẹ̀, lati gbà alafia kuro lori ilẹ aiye, ati pe ki nwọn ki o mã pa ara wọn: a si fi idà nla kan le e lọwọ.
5 Nigbati o si ṣí èdidi kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹta nwipe, Wá, wò o. Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin dúdu kan; ẹniti o joko lori rẹ̀ ni oṣuwọn awẹ́ meji li ọwọ́ rẹ̀.
6 Mo si gbọ́ bi ẹnipe ohùn kan li arin awọn ẹda alãye mẹrẹrin nì ti nwipe, Oṣuwọn alikama kan fun owo idẹ kan, ati oṣuwọn ọkà barle mẹta fun owo idẹ kan; si kiyesi i, ki o má si ṣe pa oróro ati ọti-waini lara.
7 Nigbati o si ṣí èdidi kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹda alãye kẹrin nwipe, Wá wò o.
8 Mo si wò, si kiyesi i, ẹṣin rọndọnrọndọn kan: orukọ ẹniti o joko lori rẹ̀ ni Ikú, ati Ipò-okú si tọ̀ ọ lẹhin. A si fi agbara fun wọn lori idamẹrin aiye, lati fi idà, ati ebi, ati ikú, ati ẹranko ori ilẹ aiye pa.
9 Nigbati o si ṣí èdidi karun, mo ri labẹ pẹpẹ, ọkàn awọn ti a ti pa nitori ọ̀rọ Ọlọrun, ati nitori ẹrí ti nwọn dìmu:
10 Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye?