1 NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan.
2 Mo si ri awọn angẹli meje ti nwọn duro niwaju Ọlọrun; a si fi ipè meje fun wọn.
3 Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́.
4 Ati ẹ̃fin turari na pẹlu adura awọn enia mimọ́ si gòke lọ siwaju Ọlọrun lati ọwọ́ angẹli na wá.