1 LI àtetekọṣe li Ọ̀rọ wà, Ọ̀rọ si wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si li Ọ̀rọ na.
2 On na li o wà li àtetekọṣe pẹlu Ọlọrun.
3 Nipasẹ̀ rẹ̀ li a ti da ohun gbogbo; lẹhin rẹ̀ a ko si da ohun kan ninu ohun ti a da.
4 Ninu rẹ̀ ni ìye wà; ìye na si ni imọlẹ̀ araiye.
5 Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.
6 Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu.
7 On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.