1 BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá.
2 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?
3 Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.
4 Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ.
5 Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.
6 Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na,
7 O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran.
8 Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi?
9 Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni.
10 Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là?
11 O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.
12 Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.
13 Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi.
14 Njẹ ọjọ isimi lọjọ na nigbati Jesu ṣe amọ̀ na, ti o si là a loju.
15 Nitorina awọn Farisi pẹlu tún bi i lẽre, bi o ti ṣe riran. O si wi fun wọn pe, O fi amọ̀ le oju mi, mo si wẹ̀ mo si riran.
16 Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn.
17 Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe.
18 Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju.
19 Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi?
20 Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju:
21 Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.
22 Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.
23 Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre.
24 Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe.
25 Nitorina o dahùn o si wipe, Bi ẹlẹṣẹ ni, emi kò mọ̀: ohun kan ni mo mọ̀, pe mo ti fọju ri, mo riran nisisiyi.
26 Nitorina nwọn wi fun u pe, Kili o ṣe si ọ? o ti ṣe là ọ loju?
27 O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi?
28 Nwọn si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si wipe, Iwọ li ọmọ-ẹhin rẹ̀; ṣugbọn ọmọ-ẹhin Mose li awa.
29 Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá.
30 Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju.
31 Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀.
32 Lati igba ti aiye ti ṣẹ̀, a kò ti igbọ́ pe, ẹnikan là oju ẹniti a bí li afọju rí.
33 Ibaṣepe ọkunrin yi ko ti ọdọ Ọlọrun wá, kì ba ti le ṣe ohunkohun.
34 Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode.
35 Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi?
36 On si dahùn wipe, Tani, Oluwa, ki emi ki o le gbà a gbọ́?
37 Jesu wi fun u pe, Iwọ ti ri i, on na si ni ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi.
38 O si wipe, Oluwa, mo gbagbọ́, o si wolẹ fun u.
39 Jesu si wipe, Nitori idajọ ni mo ṣe wá si aiye yi, ki awọn ti kò riran, le riran; ati ki awọn ti o riran le di afọju.
40 Ninu awọn Farisi ti o wà lọdọ rẹ̀ gbọ́ nkan wọnyi, nwọn si wi fun u pe, Awa pẹlu fọju bi?
41 Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin fọju, ẹnyin kì ba ti li ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn nisisiyi ẹnyin wipe, Awa riran; nitorina ẹ̀ṣẹ nyin wà sibẹ̀.