Joh 17 YCE

Adura Jesu

1 NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu:

2 Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u.

3 Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.

4 Emi ti yìn ọ logo li aiye: emi ti parí iṣẹ ti iwọ fifun mi lati ṣe.

5 Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.

6 Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

7 Nisisiyi nwọn mọ̀ pe, ohunkohun gbogbo ti iwọ ti fifun mi, lati ọdọ rẹ wá ni.

8 Nitori ọ̀rọ ti iwọ fifun mi, emi ti fifun wọn, nwọn si ti gbà a, nwọn si ti mọ̀ nitõtọ pe, lọdọ rẹ ni mo ti jade wá, nwọn si gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi.

9 Emi ngbadura fun wọn: emi kò gbadura fun araiye, ṣugbọn fun awọn ti iwọ ti fifun mi; nitoripe tirẹ ni nwọn iṣe.

10 Tirẹ sá ni gbogbo ohun ti iṣe temi, ati temi si ni gbogbo ohun ti iṣe tirẹ; a si ti ṣe mi logo ninu wọn.

11 Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa.

12 Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ́, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé; ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ.

13 Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn.

14 Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye.

15 Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi.

16 Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye.

17 Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ.

18 Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu.

19 Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.

20 Kì si iṣe kìki awọn wọnyi ni mo ngbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yio gbà mi gbọ́ nipa ọ̀rọ wọn;

21 Ki gbogbo nwọn ki o le jẹ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ ninu mi, ati emi ninu rẹ, ki awọn pẹlu ki o le jẹ ọ̀kan ninu wa: ki aiye ki o le gbagbọ́ pe, iwọ li o rán mi.

22 Ogo ti iwọ ti fifun mi li emi si ti fifun wọn; ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ ọ̀kan;

23 Emi ninu wọn, ati iwọ ninu mi, ki a le ṣe wọn pé li ọ̀kan; ki aiye ki o le mọ̀ pe, iwọ li o rán mi, ati pe iwọ si fẹràn wọn gẹgẹ bi iwọ ti fẹràn mi.

24 Baba, emi fẹ ki awọn ti iwọ fifun mi, ki o wà lọdọ mi, nibiti emi gbé wà; ki nwọn le mã wò ogo mi, ti iwọ ti fi fifun mi: nitori iwọ sá fẹràn mi ṣiwaju ipilẹṣẹ aiye.

25 Baba olododo, aiye kò mọ̀ ọ: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, awọn wọnyi si mọ̀ pe iwọ li o rán mi.

26 Mo ti sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun wọn, emi ó si sọ ọ di mimọ̀: ki ifẹ ti iwọ fẹràn mi, le mã wà ninu wọn, ati emi ninu wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21