Joh 16 YCE

1 NKAN wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki a má ba mu nyin kọsẹ̀.

2 Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun.

3 Nkan wọnyi ni nwọn o si ṣe, nitoriti nwọn kò mọ̀ Baba, nwọn kò si mọ̀ mi.

4 Ṣugbọn nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, pe nigbati wakati wọn ba de, ki ẹ le ranti wọn pe mo ti wi fun nyin. Ṣugbọn emi ko sọ nkan wọnyi fun nyin lati ipilẹṣẹ wá, nitoriti mo wà pẹlu nyin.

Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́

5 Ṣugbọn nisisiyi emi nlọ sọdọ ẹniti o rán mi; kò si si ẹnikan ninu nyin ti o bi mi lẽre pe, Nibo ni iwọ nlọ?

6 Ṣugbọn nitori mo sọ nkan wọnyi fun nyin, ibinujẹ kún ọkàn nyin.

7 Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; Anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.

8 Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ:

9 Niti ẹ̀ṣẹ, nitoriti nwọn kò gbà mi gbọ́;

10 Niti ododo, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba, ẹnyin kò si ri mi mọ́;

11 Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi.

12 Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.

13 Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.

14 On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.

15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.

Ìbànújẹ́ Yóo Di Ayọ̀

16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.

17 Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba?

18 Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi.

19 Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi?

20 Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Ẹnyin o ma sọkun ẹ o si ma pohùnrere ẹkún, ṣugbọn awọn araiye yio ma yọ̀: inu nyin yio si bajẹ, ṣugbọn ibinujẹ nyin li yio si di ayọ̀.

21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye.

22 Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin.

23 Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.

24 Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.

Jesu Ti Ṣẹgun Ayé

25 Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba.

26 Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin:

27 Nitoriti Baba tikararẹ̀ fẹran nyin, nitoriti ẹnyin ti fẹràn mi, ẹ si ti gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun li emi ti jade wá.

28 Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba.

29 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe.

30 Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá.

31 Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi?

32 Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi.

33 Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin tẹlẹ̀, ki ẹnyin ki o le ni alafia ninu mi. Ninu aiye, ẹnyin o ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tújuka; mo ti ṣẹgun aiye.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21