1 LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a.
2 Ajọ awọn Ju ti iṣe ajọ ìpagọ́, sunmọ etile tan.
3 Nitorina awọn arakunrin rẹ̀ wi fun u pe, Lọ kuro nihinyi, ki o si lọ si Judea, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ pẹlu ki o le ri iṣẹ rẹ ti iwọ nṣe.
4 Nitoripe kò si ẹnikẹni ti iṣe ohunkohun nikọ̀kọ, ti on tikararẹ̀ si nfẹ ki a mọ̀ on ni gbangba. Bi iwọ ba nṣe nkan wọnyi, fi ara rẹ hàn fun araiye.
5 Nitoripe awọn arakunrin rẹ̀ kò tilẹ gbà a gbọ́.
6 Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Akokò temi kò ti ide: ṣugbọn akokò ti nyin ni imura tan nigbagbogbo.
7 Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru.
8 Ẹnyin ẹ gòke lọ si ajọ yi: emi kì yio ti igoke lọ si ajọ yi; nitoriti akokò temi kò ti ide.
9 Nigbati o ti sọ nkan wọnyi fun wọn tan, o duro ni Galili sibẹ̀.
10 Ṣugbọn nigbati awọn arakunrin rẹ̀ gòke lọ tan, nigbana li on si gòke lọ si ajọ na pẹlu, kì iṣe ni gbangba, ṣugbọn bi ẹnipe nikọ̀kọ.
11 Nigbana li awọn Ju si nwá a kiri nigba ajọ, wipe, Nibo li o wà?
12 Kikùn pipọ si wà larin awọn ijọ enia nitori rẹ̀: nitori awọn kan wipe, Enia rere ni iṣe: awọn miran wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn o ntàn enia jẹ ni.
13 Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju.
14 Nigbati ajọ de arin Jesu gòke lọ si tẹmpili o si nkọ́ni.
15 Ẹnu si yà awọn Ju, nwọn wipe, ọkunrin yi ti ṣe mọ̀ iwe, nigbati ko kọ́ ẹ̀kọ́?
16 Nitorina Jesu da wọn lohùn, o si wipe, Ẹkọ́ mi ki iṣe temi, bikoṣe ti ẹniti o rán mi.
17 Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.
18 Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀.
19 Mose kò ha fi ofin fun yin, kò si ẹnikẹni ninu nyin ti o pa ofin na mọ́? Ẽṣe ti ẹnyin fi nwá ọ̀na lati pa mi?
20 Ijọ enia dahùn nwọn si wipe, Iwọ li ẹmi èṣu: tani nwá ọ̀na lati pa ọ?
21 Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, kìki iṣẹ àmi kan ni mo ṣe, ẹnu si yà gbogbo nyin.
22 Nitori eyi ni Mose fi ìkọlà fun nyin (kì iṣe nitoriti iṣe ti Mose, ṣugbọn ti awọn baba); nitorina ẹ si nkọ enia ni ilà li ọjọ isimi.
23 Bi enia ba ngbà ikọla li ọjọ isimi, ki a ma bà rú ofin Mose, ẹ ha ti ṣe mbinu si mi, nitori mo mu enia kan larada ṣáṣa li ọjọ isimi?
24 Ẹ máṣe idajọ nipa ode ara, ṣugbọn ẹ mã ṣe idajọ ododo.
25 Nigbana li awọn kan ninu awọn ara Jerusalemu wipe, Ẹniti nwọn nwá ọ̀na ati pa kọ́ yi?
26 Si wo o, o nsọrọ ni gbangba, nwọn kò si wi nkankan si i. Awọn olori ha mọ̀ nitõtọ pe, eyi ni Kristi na?
27 Ṣugbọn awa mọ̀ ibi ti ọkunrin yi gbé ti wá: ṣugbọn nigbati Kristi ba de, kò si ẹniti yio mọ̀ ibiti o gbé ti wà.
28 Nigbana ni Jesu kigbe ni tẹmpili bi o ti nkọ́ni, wipe, Ẹnyin mọ̀ mi, ẹ si mọ̀ ibiti mo ti wá: emi ko si wá fun ara mi, ṣugbọn olõtọ li ẹniti o rán mi, ẹniti ẹnyin kò mọ̀.
29 Ṣugbọn emi mọ̀ ọ: nitoripe lọdọ rẹ̀ ni mo ti wá, on li o si rán mi.
30 Nitorina nwọn nwá ọ̀na ati mú u: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e, nitoriti wakati rẹ̀ kò ti ide.
31 Ọ̀pọ ninu ijọ enia si gbà a gbọ́, nwọn si wipe, Nigbati Kristi na ba de, yio ha ṣe iṣẹ àmi jù wọnyi lọ, ti ọkunrin yi ti ṣe?
32 Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u.
33 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Niwọn igba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin, emi o si lọ sọdọ ẹniti o rán mi.
34 Ẹnyin yio wá mi, ẹnyin kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, enyin kì yio le wá.
35 Nitorina li awọn Ju mba ara wọn sọ pe, Nibo ni ọkunrin yi yio gbé lọ, ti awa kì yio fi ri i? yio ha lọ sarin awọn Hellene ti nwọn fọnká kiri, ki o si ma kọ́ awọn Hellene bi?
36 Ọrọ kili eyi ti o sọ yi, Ẹnyin ó wá mi, ẹ kì yio si ri mi: ati ibiti emi ba wà, ẹnyin kì yio le wá?
37 Lọjọ ikẹhìn, ti iṣe ọjọ nla ajọ, Jesu duro, o si kigbe, wipe, Bi òrùngbẹ ba ngbẹ ẹnikẹni, ki o tọ mi wá, ki o si mu.
38 Ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́, gẹgẹ bi iwe-mimọ́ ti wi, lati inu rẹ̀ ni odò omi ìye yio ti ma ṣàn jade wá.
39 (Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)
40 Nitorina nigbati ọ̀pọ ninu ijọ enia gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn wipe, Lotọ eyi ni woli na.
41 Awọn miran wipe, Eyi ni Kristi na. Ṣugbọn awọn kan wipe Kinla, Kristi yio ha ti Galili wá bi?
42 Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà?
43 Bẹ̃ni iyapa wà larin ijọ enia nitori rẹ̀.
44 Awọn miran ninu wọn si fé lati mu u; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e.
45 Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá?
46 Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri.
47 Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi?
48 O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́?
49 Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu.
50 Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn),
51 Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi?
52 Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili ndan? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.
53 Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.