2 Ṣugbọn ẹniti o ba ba ti ẹnu-ọ̀na wọle, on ni iṣe oluṣọ awọn agutan.
3 On ni oludèna ṣilẹkun fun; awọn agutan si gbọ ohùn rẹ̀: o si pè awọn agutan tirẹ̀ li orukọ, o si ṣe amọ̀na wọn jade.
4 Nigbati o si mu awọn agutan tirẹ̀ jade, o ṣiwaju wọn, awọn agutan si ntọ̀ ọ lẹhin: nitoriti nwọn mọ̀ ohùn rẹ̀.
5 Nwọn kò jẹ tọ̀ alejò lẹhin, ṣugbọn nwọn a ma sá lọdọ rẹ̀: nitoriti nwọn kò mọ̀ ohùn alejò.
6 Owe yi ni Jesu pa fun wọn: ṣugbọn òye ohun ti nkan wọnni jẹ ti o nsọ fun wọn kò yé wọn.
7 Nitorina Jesu tún wi fun wọn pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Emi ni ilẹkun awọn agutan.
8 Olè ati ọlọṣà ni gbogbo awọn ti o ti wá ṣiwaju mi: ṣugbọn awọn agutan kò gbọ́ ti wọn.