1 ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀.
2 (Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.)
3 Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da.
4 Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀.