12 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn.
13 Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun.
14 Nigbana ni Jesu wi fun wọn gbangba pe, Lasaru kú.
15 Emi si yọ̀ nitori nyin, ti emi kò si nibẹ̀, Ki ẹ le gbagbọ́; ṣugbọn ẹ jẹ ki a lọ sọdọ rẹ̀.
16 Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.
17 Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe a ti tẹ́ ẹ sinu ibojì ni ijọ mẹrin na.
18 Njẹ Betani sunmọ Jerusalemu to furlongi mẹdogun: