16 Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu.
17 Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe a ti tẹ́ ẹ sinu ibojì ni ijọ mẹrin na.
18 Njẹ Betani sunmọ Jerusalemu to furlongi mẹdogun:
19 Ọ̀pọ ninu awọn Ju si wá sọdọ Marta ati Maria, lati tù wọn ninu nitori ti arakunrin wọn.
20 Nitorina nigbati Marta gbọ́ pe Jesu mbọ̀ wá, o jade lọ ipade rẹ̀: ṣugbọn Maria joko ninu ile.
21 Nigbana ni Marta wi fun Jesu pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kì ba tí kú.
22 Ṣugbọn nisisiyi na, mo mọ̀ pe, ohunkohun ti iwọ ba bère lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yio fifun ọ.