7 Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea.
8 Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀?
9 Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi.
10 Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀.
11 Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀.
12 Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn.
13 Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun.