27 Nisisiyi li a npọ́n ọkàn mi loju; kili emi o si wi? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yi: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yi.
28 Baba, ṣe orukọ rẹ logo. Nitorina ohùn kan ti ọrun wá, wipe, Emi ti ṣe e logo na, emi o si tún ṣe e logo.
29 Nitorina ijọ enia ti o duro nibẹ̀, ti nwọn si gbọ́ ọ, wipe, Ãrá nsán: awọn ẹlomiran wipe, Angẹli kan li o mba a sọrọ.
30 Jesu si dahùn wipe, Ki iṣe nitori mi li ohùn yi ṣe wá, bikoṣe nitori nyin.
31 Nisisiyi ni idajọ aiye yi de: nisisiyi li a o lé alade aiye yi jade.
32 Ati emi, bi a ba gbé mi soke kuro li aiye, emi o fà gbogbo enia sọdọ ara mi.
33 Ṣugbọn o wi eyi, o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.