26 Ṣugbọn Olutunu na, Ẹmí Mimọ́, ẹniti Baba yio rán li orukọ mi, on ni yio kọ́ nyin li ohun gbogbo, yio si rán nyin leti ohun gbogbo ti mo ti sọ fun nyin.
27 Alafia ni mo fi silẹ fun nyin, alafia mi ni mo fifun nyin: kì iṣe gẹgẹ bi aiye iti fi funni li emi fifun nyin. Ẹ máṣe jẹ ki okàn nyin daru, ẹ má si jẹ ki o warìri.
28 Ẹnyin sá ti gbọ́ bi mo ti wi fun nyin pe, Emi nlọ, emi ó si tọ̀ nyin wá. Ibaṣepe ẹnyin fẹràn mi, ẹnyin iba yọ̀ nitori emi nlọ sọdọ Baba: nitori Baba mi tobi jù mi lọ.
29 Emi si ti sọ fun nyin nisisiyi ki o to ṣẹ, pe nigbati o ba ṣẹ, ki ẹ le gbagbọ́.
30 Emi kì o ba nyin sọ̀rọ pipọ: nitori aladé aiye yi wá, kò si ni nkankan lọdọ mi.
31 Ṣugbọn nitori ki aiye le mọ̀ pe emi fẹràn Baba; gẹgẹ bi Baba si ti fi aṣẹ fun mi, bẹ̃ni emi nṣe. Ẹ dide, ẹ jẹ ki a lọ kuro nihinyi.