12 Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.
13 Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.
14 On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.
15 Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.
16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.
17 Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba?
18 Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi.