1 NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
2 Judasi, ẹniti o fi i hàn, si mọ̀ ibẹ̀ pẹlu: nitori nigba-pupọ ni Jesu ima lọ sibẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
3 Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.
4 Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá?
5 Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn.