17 Nitorina nwọn mu Jesu, o si jade lọ, o rù agbelebu fun ara rẹ̀ si ibi ti a npè ni Ibi-agbari, li ede Heberu ti a npè ni Golgota:
18 Nibiti nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn meji miran pẹlu rẹ̀, niha ikini ati nìha keji, Jesu si wà larin.
19 Pilatu si kọ iwe akọle kan pẹlu, o si fi i le ori agbelebu na. Ohun ti a si kọ ni, JESU TI NASARETI ỌBA AWỌN JU.
20 Nitorina ọpọ awọn Ju li o kà iwe akọle yi: nitori ibi ti a gbé kàn Jesu mọ agbelebu sunmọ eti ilu: a si kọ ọ li ède Heberu, ati ti Latini, ati ti Helene.
21 Nitorina awọn olori alufa awọn Ju wi fun Pilatu pe, Máṣe kọ ọ pe, Ọba awọn Ju; ṣugbọn pe on wipe, Emi li Ọba awọn Ju.
22 Pilatu dahùn pe, Ohun ti mo ti kọ tan, mo ti kọ na.
23 Nigbana li awọn ọmọ-ogun, nigbati nwọn kàn jesu mọ agbelebu tan, nwọn mu aṣọ rẹ̀, nwọn si pín wọn si ipa mẹrin, apakan fun ọmọ-ogun kọkan, ati àwọtẹlẹ rẹ̀: ṣugbọn àwọ̀tẹlẹ na kò li ojuran, nwọn hun u lati oke titi jalẹ.