5 Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na!
6 Nitorina nigbati awọn olori alufa, ati awọn onṣẹ ri i, nwọn kigbe wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u fun ara nyin, ki ẹ si kàn a mọ agbelebu: nitoriti emi ko ri ẹ̀ṣẹ lọwọ rẹ̀.
7 Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.
8 Nitorina nigbati Pilatu gbọ́ ọ̀rọ yi ẹ̀ru tubọ ba a.
9 O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn.
10 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu?
11 Jesu da a lohun pe, Iwọ kì ba ti li agbara kan lori mi, bikoṣepe a fi i fun ọ lati oke wá: nitorina ẹniti o fi mi le ọ lọwọ li o ni ẹ̀ṣẹ pọ̀ju.