1 LI ọjọ ikini ọ̀sẹ ni kùtùkùtù nigbati ilẹ kò ti imọ́, ni Maria Magdalene wá si ibojì, o si ri pe, a ti gbé okuta kuro li ẹnu ibojì.
2 Nitorina o sare, o si tọ̀ Simoni Peteru wá, ati ọmọ-ẹhin miran na ẹniti Jesu fẹran, o si wi fun wọn pe, Nwọn ti gbé Oluwa kuro ninu ibojì, awa kò si mọ̀ ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.
3 Nigbana ni Peteru jade, ati ọmọ-ẹhin miran na, nwọn si wá si ibojì.
4 Awọn mejeji si jùmọ sare: eyi ọmọ-ẹhin miran nì si sare yà Peteru, o si tètekọ de ibojì.
5 O si bẹ̀rẹ, o si wò inu rẹ̀, o ri aṣọ ọgbọ na lelẹ; ṣugbọn on kò wọ̀ inu rẹ̀.
6 Nigbana ni Simoni Peteru ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀ de, o si wọ̀ inu ibojì, o si ri aṣọ ọ̀gbọ na wà nilẹ̀.
7 Ati pe gèle, ti o wà nibi ori rẹ̀, kò si wà pẹlu aṣọ ọgbọ na, ṣugbọn a ká a jọ ni ibikan fun ara rẹ̀.