6 Nigbana ni Simoni Peteru ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀ de, o si wọ̀ inu ibojì, o si ri aṣọ ọ̀gbọ na wà nilẹ̀.
7 Ati pe gèle, ti o wà nibi ori rẹ̀, kò si wà pẹlu aṣọ ọgbọ na, ṣugbọn a ká a jọ ni ibikan fun ara rẹ̀.
8 Nigbana li ọmọ-ẹhin miran na, ẹniti o kọ de ibojì, wọ̀ inu rẹ̀ pẹlu, o si ri, o si gbagbọ́.
9 Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú.
10 Bẹli awọn ọmọ-ẹhin na si tun pada lọ si ile wọn.
11 Ṣugbọn Maria duro leti ibojì lode, o nsọkun: bi o ti nsọkun, bẹli o bẹ̀rẹ, o si wò inu ibojì.
12 O si kiyesi awọn angẹli meji alaṣọ funfun, nwọn joko, ọkan niha ori, ati ọkan niha ẹsẹ̀, nibiti oku Jesu gbé ti sùn si.