16 Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.
17 Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là.
18 Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́.
19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.
20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.
21 Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.
22 Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi.