22 Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi.
23 Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.
24 Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu.
25 Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu.
26 Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.
27 Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.
28 Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.