29 Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.
30 On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.
31 Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ.
32 Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀.
33 Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.
34 Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn.
35 Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ.