33 Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.
34 Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn.
35 Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ.
36 Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.