14 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.
15 Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin.
16 Jesu wi fun u pe, Lọ ipè ọkọ rẹ, ki o si wá si ihinyi.
17 Obinrin na dahùn, o si wi fun u pe, Emi kò li ọkọ. Jesu wi fun u pe, Iwọ wi rere pe, emi kò li ọkọ:
18 Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini.
19 Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.
20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.