2 (Ṣugbọn Jesu tikararẹ̀ kò baptisi bikoṣe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,)
3 O fi Judea silẹ, o si tún lọ si Galili.
4 On kò si le ṣaima kọja lãrin Samaria.
5 Nigbana li o de ilu Samaria kan, ti a npè ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ biri nì, ti Jakọbu ti fifun Josefu, ọmọ rẹ̀.
6 Kanga Jakọbu si wà nibẹ̀. Nitorina bi o ti rẹ̀ Jesu tan nitori ìrin rẹ̀, bẹ̀li o joko leti kanga: o si jẹ ìwọn wakati kẹfa ọjọ.
7 Obinrin kan, ara Samaria, si wá lati pọn omi: Jesu wi fun u pe, Fun mi mu.
8 (Nitori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ti lọ si ilu lọ irà onjẹ.)