25 Obinrin na wi fun u pe, mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.
26 Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on.
27 Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ?
28 Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe,
29 Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?
30 Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá.
31 Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun.