3 Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi.
4 Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni.
5 Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji.
6 Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi?
7 Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi.
8 Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin.
9 Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi.