32 Ẹlomiran li ẹniti njẹri mi; emi si mọ̀ pe, otitọ li ẹrí mi ti o jẹ́.
33 Ẹnyin ti ranṣẹ lọ sọdọ Johanu, on si ti jẹri si otitọ.
34 Ṣugbọn emi kò gba ẹrí lọdọ enia: ṣugbọn nkan wọnyi li emi nsọ, ki ẹnyin ki o le là.
35 On ni fitila ti o njó, ti o si ntànmọlẹ: ẹnyin si fẹ fun sã kan lati mã yọ̀ ninu imọlẹ rẹ̀.
36 Ṣugbọn emi ni ẹri ti o pọ̀ju ti Johanu lọ: nitori iṣẹ ti Baba ti fifun mi lati ṣe pari, iṣẹ na pãpã ti emi nṣe ni njẹri mi pe, Baba li o rán mi.
37 Ati Baba ti o rán mi ti jẹri mi. Ẹnyin kò gbọ́ ohùn rẹ̀ nigba kan ri, bẹ̃li ẹ kò ri àwọ rẹ̀.
38 Ẹ kò si ni ọ̀rọ rẹ̀ lati ma gbé inu nyin: nitori ẹniti o rán, on li ẹnyin kò gbagbọ́.