8 Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin.
9 Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi.
10 Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ.
11 O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn.
12 Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?
13 Ẹniti a mu larada na kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuto nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀.
14 Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ.