6 O si sọ eyi lati dán a wò; nitoriti on tikararẹ̀ mọ̀ ohun ti on ó ṣe.
7 Filippi da a lohùn pe, Akara igba owo idẹ ko to fun wọn, ti olukuluku wọn iba fi mu diẹ-diẹ.
8 Ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Anderu, arakunrin Simoni Peteru wi fun u pe,
9 Ọmọdekunrin kan mbẹ nihinyi, ti o ni iṣu akara barle marun, ati ẹja kékèké meji: ṣugbọn kini wọnyi jẹ lãrin ọ̀pọ enia wọnyi bi eyi?
10 Jesu si wipe, Ẹ mu ki awọn enia na joko. Koriko pipọ si wà nibẹ̀. Bẹ̃li awọn ọkunrin na joko, ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia ni iye.
11 Jesu si mu iṣu akara wọnni; nigbati o si ti dupẹ, o pin wọn fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si pín wọn fun awọn ti o joko; bẹ̃ gẹgẹ si li ẹja ni ìwọn bi nwọn ti nfẹ.
12 Nigbati nwọn si yó, o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ kó ajẹkù ti o kù jọ, ki ohunkohun máṣe ṣegbé.