30 Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.
31 Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ.
32 Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.
33 Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira?
34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.
35 Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai.
36 Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ.