32 Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.
33 Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira?
34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.
35 Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai.
36 Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ.
37 Mo mọ̀ pe irú-ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe; ṣugbọn ẹ nwá ọ̀na ati pa mi, nitori ọ̀rọ mi kò ri àye ninu nyin.
38 Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin.