20 O si dahùn o si wi fun wọn pe, Ọkan ninu awọn mejila ni, ti o ntọwọ bọ̀ inu awo pẹlu mi.
21 Nitõtọ Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a kò bí i.
22 Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun wọn, o wipe, Gbà, jẹ: eyiyi li ara mi.
23 O si gbe ago, nigbati o si sure tan, o fifun wọn: gbogbo nwọn si mu ninu rẹ̀.
24 O si wi fun wọn pe, Eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia.
25 Lõtọ ni mo wi fun nyin, emi kì yio mu ninu eso ajara mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o mu u ni titun ni ijọba Ọlọrun.
26 Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.