26 Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.
27 Jesu si wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru oni: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o lù oluṣọ agutan, a o si tú agbo agutan ká kiri.
28 Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili.
29 Ṣugbọn Peteru wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀, ṣugbọn emi kọ́.
30 Jesu si wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, loni yi, ani li alẹ yi, ki akukọ ki o to kọ nigba meji, iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta.
31 Ṣugbọn o tẹnumọ ọ gidigidi wipe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi ko jẹ sẹ́ ọ bi o ti wù ki o ri. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo wọn wi pẹlu.
32 Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura.