4 Awọn kan si wà ti inu wọn ru ninu ara wọn, nwọn si wipe, Nitori kili a ṣe nfi ororo ikunra yi ṣòfo?
5 A ba sá tà ororo ikunra yi jù ìwọn ọ̃dunrun owo idẹ lọ a ba si fifun awọn talakà. Nwọn si nkùn si i.
6 Ṣugbọn Jesu wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẽṣe ti ẹnyin fi mba a wi? iṣẹ rere li o ṣe si mì lara.
7 Nigbagbogbo li ẹnyin sá ni talakà pẹlu nyin, ẹnyin le ma ṣore fun wọn nigbakugba ti ẹnyin fẹ; ṣugbọn emi li ẹnyin kó ni nigbagbogbo.
8 O ṣe eyi ti o le ṣe: o wá ṣiwaju lati fi oróro kùn ara mi fun sisinku mi.
9 Lõtọ ni mo wi fun nyin, Nibikibi ti a o gbé wasu ihinrere yi ni gbogbo aiye, nibẹ̀ pẹlu li a o si rò ihin eyi ti obinrin yi ṣe lati fi ṣe iranti rẹ̀.
10 Judasi Iskariotu, ọkan ninu awọn mejila, si tọ̀ awọn olori alufa lọ, lati fi i le wọn lọwọ.