42 Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi.
43 Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá.
44 Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia.
45 Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
46 Nwọn si gbé ọwọ́ wọn le e, nwọn si mu u.
47 Ṣugbọn ọkan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ fà idà yọ, o si sá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí rẹ̀ kuro.
48 Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu?