49 Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ.
50 Gbogbo wọn si fi i silẹ, nwọn si sá lọ.
51 Ọmọkunrin kan si ntọ̀ ọ lẹhin, ti o fi aṣọ ọgbọ bò ìhoho rẹ̀; awọn ọmọ-ogun si gbá a mu:
52 O si jọwọ aṣọ ọgbọ na lọwọ, o si sá kuro lọdọ wọn nihoho.
53 Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀.
54 Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána.
55 Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan.