8 Nwọn si jade lọ kánkan, nwọn si sá kuro ni ibojì; nitoriti nwọn nwarìri, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi: bẹ̃ni nwọn ko wi ohunkohun fun ẹnikan; nitoripe ẹ̀ru ba wọn.
9 Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade.
10 On si lọ sọ fun awọn ti o ti mba a gbé, bi nwọn ti ngbàwẹ, ti nwọn si nsọkun.
11 Ati awọn, nigbati nwọn si gbọ́ pe o ti di alãye, ati pe, on si ti ri i, nwọn kò gbagbọ.
12 Lẹhin eyini, o si fi ara hàn fun awọn meji ninu wọn li ọna miran, bi nwọn ti nrìn li ọ̀na, ti nwọn si nlọ si igberiko.
13 Nwọn si lọ isọ fun awọn iyokù: nwọn kò si gbà wọn gbọ́ pelu.
14 Lẹhinna o si fi ara hàn fun awọn mọkanla bi nwọn ti joko tì onje, o si ba aigbagbọ́ ati lile àiya wọn wi, nitoriti nwọn ko gbà awọn ti o ti ri i gbọ́ lẹhin igbati o jinde.