1 AWỌN Farisi si pejọ sọdọ rẹ̀, ati awọn kan ninu awọn akọwe ti nwọn ti Jerusalemu wá.
2 Nigbati nwọn ri omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nfi ọwọ aimọ́ jẹun, eyini ni li aiwẹ̀ ọwọ́, nwọn mba wọn wijọ.
3 Nitori awọn Farisi, ati gbogbo awọn Ju, bi nwọn ko ba wẹ̀ ọwọ́ wọn gidigidi, nwọn ki ijẹun, nitoriti nwọn npa ofin atọwọdọwọ awọn àgba mọ́.
4 Nigbati nwọn ba si ti ọjà bọ̀, bi nwọn ko ba wẹ̀, nwọn ki ijẹun, ọ̀pọlọpọ ohun miran li o si wà, ti nwọn ti gbà lati mã fiyesi, bi fifọ ago, ati ikòko, ati ohunèlo idẹ, ati akete.
5 Nigbana li awọn Farisi ati awọn akọwe bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ ko rìn gẹgẹ bi ofin atọwọdọwọ awọn àgba, ṣugbọn nwọn nfi ọwọ aimọ́ jẹun?
6 O dahùn o si wi fun wọn pe, Otitọ ni Isaiah sọtẹlẹ nipa ti ẹnyin agabagebe, bi a ti kọ ọ pe, Awọn enia yi nfi ète wọn bọla fun mi, ṣugbọn ọkàn wọn jìna si mi.
7 Ṣugbọn lasan ni nwọn ntẹriba fun mi, ti nwọn nfi ofin enia kọ́ni fun ẹkọ́.