10 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan:
11 Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.
12 Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan.
13 Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn:
14 Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro:
15 Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ:
16 Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn: